Exodus 17:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ongbẹ omi si ngbẹ awọn enia na nibẹ̀; awọn enia na si nkùn si Mose, nwọn si wipe, Ẽtiri ti iwọ fi mú wa goke lati Egipti wá, lati fi ongbẹ pa wa ati awọn ọmọ wa, ati ẹran wa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n òùngbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Éjíbítì láti mú kí òùngbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òùngbẹ.”