Exodus 17:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si wi fun Joṣua pe, Yàn enia fun wa, ki o si jade lọ ibá Amaleki jà: li ọla li emi o duro lori oke ti emi ti ọpá Ọlọrun li ọwọ́ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì sọ fún Jọ́súà pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Ámélékì jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.”