Exodus 18:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Fetisilẹ nisisiyi si ohùn mi; emi o fun ọ ni ìmọ, Ọlọrun yio si pẹlu rẹ: iwọ wà niwaju Ọlọrun fun awọn enia yi, ki iwọ ki o ma mú ọ̀ran wọn wá si ọdọ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìnyìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè àìyedè wá sí iwájú rẹ̀.