Exodus 18:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu iwọ o si ṣà ninu gbogbo awọn enia yi awọn ọkunrin ti o to, ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awọn ọkunrin olõtọ, ti o korira ojukokoro; irú awọn wọnni ni ki o fi jẹ́ olori wọn, lati ṣe olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwamẹwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sà àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n se olórí: lórí ẹgbẹ̀rún-ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-un, àádọ́ta-àádọ́ta àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.