Exodus 18:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jẹ́ kí wọn máa ṣe onídàájọ́ fún àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá jẹ́ pataki pataki nìkan ni wọn yóo máa kó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọ́n máa parí àwọn ẹjọ́ kéékèèké láàrin ara wọn. Èyí yóo mú kí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọn yóo sì máa bá ọ gbé ninu ẹrù náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia nigbakugba: yio si ṣe, gbogbo ẹjọ́ nla ni ki nwọn ki o ma mú tọ̀ ọ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ́ kekeké ni ki nwọn ki o ma dá: yio si rọrùn fun iwọ tikalarẹ, nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe.