Exodus 18:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Ọlọrun bá gbà fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ṣe é, ẹ̀mí rẹ yóo gùn, gbogbo àwọn eniyan wọnyi náà yóo sì pada sí ilé wọn ní alaafia.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ ba jẹ ṣe nkan yi, bi Ọlọrun ba si fi aṣẹ fun ọ bẹ̃, njẹ iwọ o le duro pẹ, ati gbogbo awọn enia yi pẹlu ni yio si dé ipò wọn li alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni ìtẹ́lọ́rùn.”