Exodus 18:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè ṣe alákòóso ninu àwọn eniyan Israẹli, ó fi wọ́n ṣe olórí àwọn eniyan náà, àwọn kan jẹ́ alákòóso fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn, fún ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn, fún araadọta, àwọn mìíràn fún eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si yàn awọn enia ti o to ninu gbogbo Israeli, o si fi wọn ṣe olori awọn enia, olori ẹgbẹgbẹrun, olori ọrọrún, olori arãdọta, olori mẹwamẹwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mósè sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kun ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì; ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rùn, ọgọ́rùn ún ọgọ́rùn ún, àádọ́ta-àádọ́ta, àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.