Exodus 18:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jẹtiro sì bá wọn yọ̀ nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí gbígbà tí ó gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jetro si yọ̀ nitori gbogbo ore ti OLUWA ti ṣe fun Israeli, ẹniti o ti gbàla lọwọ awọn ara Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Inú Jẹ́tírò dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti OLÚWA ṣe fún Ísírẹ́lì, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.