Exodus 19:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si sagbàra fun awọn enia yiká, pe, Ẹ ma kiyesi ara nyin, ki ẹ máṣe gùn ori oke lọ, ki ẹ má si ṣe fọwọbà eti rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn oke na, pipa ni nitõtọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ìwọ kí ó se ààlà fún àwọn ènìyàn, ibi tí wọn lè dé dúró, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣọ́ra! Ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ máa tilẹ̀ fi ọwọ́ kan etí ààlà rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà yóò kú: