Exodus 19:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá bẹ̀rẹ̀ sí sán, bẹ́ẹ̀ ni mànàmáná ń kọ, ìkùukùu sì bo òkè náà mọ́lẹ̀, fèrè kan dún tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo eniyan tí wọ́n wà ninu àgọ́ wárìrì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, li owurọ̀ ijọ́ kẹta, ni ãrá ati mànamána wà, ati awọsanma ṣíṣu dùdu lori òke na, ati ohùn ipè na si ndún kikankikan; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti o wà ni ibudó warìri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹ́ta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó sú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkan kíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì.