Exodus 19:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sì wí fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o mú Aaroni gòkè wá, ṣugbọn má ṣe jẹ́ kí àwọn alufaa ati àwọn eniyan náà rọ́ wá sórí òkè níbi tí mo wà, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun u pe, Lọ, sọkalẹ; ki iwọ ki o si goke wá, iwọ ati Aaroni pẹlu rẹ: ṣugbọn ki awọn alufa ati awọn enia ki o máṣe yà lati goke tọ̀ OLUWA wá, ki o má ba kọlù wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì wí fún Mósè pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Árónì gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ OLÚWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”