Exodus 19:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn eniyan náà bá pa ohùn pọ̀, wọ́n ní, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá lọ sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn enia na si jùmọ dahùn, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si mú ọ̀rọ awọn enia pada tọ̀ OLUWA lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò se ohun gbogbo ti OLÚWA wí.” Mósè sì mú ìdáhùn wọn padà tọ OLÚWA lọ.