Exodus 19:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ fún Mose pé, “Mò ń tọ̀ ọ́ bọ̀ ninu ìkùukùu tí yóo bo gbogbo ilẹ̀, kí àwọn eniyan náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè gbà ọ́ gbọ́ títí lae.” Mose sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi tọ̀ ọ wá ninu awọsanma ṣíṣu, ki awọn enia ki o le ma gbọ́ nigbati mo ba mbá ọ sọ̀rọ, ki nwọn ki o si ma gbà ọ gbọ́ pẹlu lailai. Mose si sọ ọ̀rọ awọn enia na fun OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu síṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mósè sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún OLÚWA.