Exodus 2:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Mose dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ó sì rí i bí ìyà tí ń jẹ wọ́n. Ó rí i tí ará Ijipti kan ń lu ọ̀kan ninu àwọn Heberu, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọjọ́ wọnni, ti Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò iṣẹ wọn: o si ri ara Egipti kan o nlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mósè ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Éjíbítì tí ń lu ará Ébérù, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.