Exodus 2:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó tún jáde lọ ní ọjọ́ keji, ó rí i tí àwọn Heberu meji ń jà; ó bá bi ẹni tí ó jẹ̀bi pé, “Kí ló dé tí o fi ń lu ẹnìkejì rẹ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si jade lọ ni ijọ́ keji, kiyesi i, ọkunrin meji ara Heberu mbá ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o firan si ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Hébérù méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Hébérù arákùnrin rẹ?”