Exodus 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin náà dáhùn pé, “Ta ló fi ọ́ jẹ olórí ati onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa èmi náà bí o ti pa ará Ijipti níjelòó ni?” Ẹ̀rù ba Mose, ó sì rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Láìsí àní àní, ọ̀rọ̀ yìí ti di mímọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Tali o fi ọ jẹ́ olori ati onidajọ lori wa? iwọ fẹ́ pa mi bi o ti pa ara Egipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ ọ̀ran yi di mimọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Éjíbítì?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mósè, ó rò nínú ara rẹ̀ pé “ó ní láti jẹ́ wí pé ohun tí mo ṣe yìí ti di mímọ̀.”