Exodus 2:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọbinrin meje kan wá pọn omi, wọ́n jẹ́ ọmọ Jẹtiro, alufaa ìlú Midiani. Wọ́n pọn omi kún ọpọ́n ìmumi àwọn ẹran, láti fún àwọn agbo ẹran baba wọn ní omi mu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, àlùfáà Mídíánì kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.