Exodus 2:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn olùṣọ́-aguntan dé, wọ́n lé àwọn ọmọbinrin meje náà sẹ́yìn; ṣugbọn Mose dìde, ó ran àwọn ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ó sì fún àwọn ẹran wọn ní omi mu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn kuro: nigbana ni Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fi omi fun agbo-ẹran wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn darandaran kán wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mósè dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.