Exodus 2:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Reueli bá bi àwọn ọmọ rẹ̀ léèrè pé, “Níbo ni ará Ijipti ọ̀hún wà? Kí ló dé tí ẹ fi sílẹ̀? Ẹ lọ pè é wọlé, kí ó wá jẹun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe Nibo li o gbé wà? ẽṣe ti ẹnyin fi ọkunrin na silẹ? ẹ pè e ki o le wá ijẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sọ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, “Níbo ni ó wà? Èéṣe ti ẹ fi fi ọkùnrin náà sílẹ̀? Ẹ pè é wá jẹun.”