Exodus 2:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, ọba Ijipti kú, àwọn ọmọ Israẹli sì ń kérora ní oko ẹrú tí wọ́n wà, wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Igbe tí wọn ń ké ní oko ẹrú sì gòkè tọ OLUWA lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe lẹhin ọjọ́ pupọ̀, ti ọba Egipti kú: awọn ọmọ Israeli si ngbin nitori ìsin na, nwọn si ke, igbe wọn si goke tọ̀ Ọlọrun lọ nitori ìsin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Éjíbítì kú. Àwọn ará Ísírẹ́lì ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.