Exodus 20:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí olukuluku níláti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà; olukuluku yín ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹrú rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, ati ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati àlejò tí ó wà ninu ilé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọjọ́ keje li ijọ́ isimi OLUWA Ọlọrun rẹ: ninu rẹ̀ iwọ kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ohunọ̀sin rẹ, ati alejò rẹ̀ ti mbẹ ninu ibode rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi OLÚWA Ọlọ́run rẹ. Nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kiṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkunrìn àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ tó wà ní nínú ibodè rẹ.