Exodus 20:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, ọjọ́ mẹfa ni èmi OLUWA fi dá ọ̀run ati ayé, ati òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn; mo sì sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni mo ṣe bukun ọjọ́ ìsinmi náà, tí mo sì yà á sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o si simi ni ijọ́ keje: nitorina li OLUWA ṣe busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé, òkun àti gbogbo nǹkan tí ó wà nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni OLÚWA ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.