Exodus 20:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn eniyan náà gbọ́ bí ààrá ti ń sán, tí wọ́n rí i bí mànàmáná ti ń kọ, tí wọ́n gbọ́ dídún ìró fèrè, tí wọ́n rí i tí òkè ń rú èéfín, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wárìrì. Wọ́n dúró lókèèrè,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn enia na si ri ãrá na, ati mànamána na, ati ohùn ipè na, nwọn ri oke na nṣe ẽfi: nigbati awọn enia si ri i, nwọn ṣí, nwọn duro li òkere rére.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n sìgàsìgà fún ìbẹ̀rù.