Exodus 21:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
bí ẹni tí wọ́n lù tí ó farapa náà bá dìde, tí ó sì ń fi ọ̀pá rìn kiri, ẹni tí ó lù ú bọ́ lọ́wọ́ ikú, ṣugbọn dandan ni kí ó san owó fún àkókò tí ẹni tí ó lù náà lò ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, kí ó sì ṣe ètò ìtọ́jú rẹ̀ títí yóo fi sàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtilẹ̀ ní ọwọ rẹ̀ rìn káàkiri. Ẹni náà ni láti san owo ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá.