Exodus 21:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí àwọn eniyan bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe aboyún léṣe, tóbẹ́ẹ̀ tí oyún rẹ̀ bàjẹ́ mọ́ ọn lára, ṣugbọn tí òun gan-an kò kú, ẹni tí ó ṣe aboyún náà léṣe níláti san iyekíye tí ọkọ rẹ̀ bá sọ pé òun yóo gbà bí owó ìtanràn, tí onídàájọ́ bá ti fi ọwọ́ sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ọkunrin ba njà, ti nwọn si pa obinrin aboyún lara, tobẹ̃ ti oyún rẹ̀ ṣẹ́, ṣugbọn ti ibi miran kò si pẹlu: a o mu ki o san nitõtọ, gẹgẹ bi ọkọ obinrin na yio ti dá lé e; on o si san a niwaju onidajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí àwọn ènìyàn ti ń jà bá pa aboyún lára, tí aboyún náà bá bimọ láìpé ọjọ́, ṣùgbọ́n ti kò sí aburú mìíràn mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ẹni ti ó fa ìpalára yìí yóò san iyekíye ti ọkọ aboyún náà bá béèrè fún, bí ilé ẹjọ́ bá se gbà láàyè gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.