Exodus 21:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ẹnìkan bá gbá ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ lójú, tí ojú náà sì fọ́, olúwarẹ̀ yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí pé ó ti fọ́ ọ lójú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba ṣepe ẹnikan ba lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi ẹrú rẹ̀ obinrin li oju ti o si fọ́; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori oju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtanràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́.