Exodus 21:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó bá yọ eyín ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀, yóo dá ẹrú náà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé ó ti yọ ọ́ léyín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si ká ehín ẹrú rẹ̀ ọkunrin, tabi ehín ẹrú rẹ̀ obinrin; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori ehín rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá sì lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ti eyín rẹ̀ fi ká, ó ni láti jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira ni ìtanran fún eyín rẹ̀ tí ó ká.