Exodus 21:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí mààlúù bá kan eniyan pa, kí wọ́n sọ mààlúù náà ní òkúta pa. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ ẹni tí ó ni mààlúù náà níyà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi akọmalu ba kàn ọkunrin tabi obinrin ti o si kú: sísọ ni ki a sọ akọmalu na li okuta pa bi o ti wù ki o ṣe, ki a má si ṣe jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn ọrùn oni-akọmalu na yio mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí akọ màlúù bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò ní dá ẹni tí ó ni akọ màlúù náà lẹ́bi, ọrùn rẹ̀ yóò sì mọ́.