Exodus 21:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ mààlúù náà ti kan eniyan tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún ẹni tí ó ni ín, tí kò sì so ó mọ́lẹ̀, bí ó bá pa eniyan, kí wọn sọ mààlúù náà ní òkúta pa, kí wọn sì pa ẹni tí ó ni ín pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ba ṣepe akọmalu na a ti ma fi iwo rẹ̀ kàn nigba atijọ, ti a si ti kìlọ fun oluwa rẹ̀, ti kò si sé e mọ, ṣugbọn ti o pa ọkunrin tabi obinrin, akọmalu na li a o sọ li okuta pa, oluwa rẹ̀ li a o si lù pa pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo ti akọ màlúù náà ti máa ń kan ènìyàn, tí a sì ti ń kìlọ̀ fún olówó rẹ̀, ti olówó rẹ̀ kò sì mú un so, tí ó bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a ó sì pa olówó rẹ̀ pẹ̀lú.