Exodus 21:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé mààlúù yìí ti máa ń kàn tẹ́lẹ̀, tí ẹni tí ó ni ín kò sì mú un so, yóo fi mààlúù mìíràn rọ́pò èyí tí mààlúù rẹ̀ pa, òkú mààlúù yóo sì di tirẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tabi bi a ba si mọ̀ pe akọmalu na a ti ma kàn nigba atijọ ti oluwa rẹ̀ kò sé e mọ́; on o fi akọmalu san akọmalu nitõtọ; okú a si jẹ́ tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo tí akọ màlúù náà máa ń kan òmíràn, tí olówó rẹ̀ kò sì mú un so, olówó rẹ̀ yóò san ẹran dípò ẹran. Ẹran tí ó kú yóò sì jẹ́ tirẹ̀.