Exodus 21:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
olówó rẹ̀ yóo mú un wá siwaju Ọlọrun, ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ tabi òpó ìlẹ̀kùn, olówó rẹ̀ yóo fi òòlù lu ihò sí etí rẹ̀, ẹrú náà yóo sì di tirẹ̀ títí ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki oluwa rẹ̀ ki o mú u lọ sọdọ awọn onidajọ; yio si mú u lọ si ẹnu-ọ̀na, tabi si opó ẹnu-ọ̀na; oluwa rẹ̀ yio si fi olù lú u li eti; on a si ma sìn i titi aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni olówó rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdàjọ́. Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu ọ̀nà tàbí lọ sí ibi òpó, yóò sì fi ìlutí lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé.