Exodus 21:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹrubinrin yìí kò bá wù olówó rẹ̀ láti fi ṣe aya, ó níláti dá a pada fún baba rẹ̀, baba rẹ̀ yóo sì rà á pada. Olówó rẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á fún àjèjì nítorí pé òun ló kọ̀ tí kò ṣe ẹ̀tọ́ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àwọn èniyàn orílẹ̀ èdè mìíràn, nítorí pé òun ni kò se ojúse rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà.