Exodus 22:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ẹnìkan bá jí akọ mààlúù kan tabi aguntan kan gbé, tí ó bá pa á, tabi tí ó tà á, yóo san akọ mààlúù marun-un dípò ẹyọ kan ati aguntan mẹrin dípò aguntan kan. Tí kò bá ní ohun tí yóo fi tán ọ̀ràn náà, wọn yóo ta òun fúnra rẹ̀ láti san ohun tí ó jí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
BI ọkunrin kan ba ji akọmalu, tabi agutan kan, ti o si pa a, tabi ti o tà a; yio san akọmalu marun dipò akọmalu kan, ati agutan mẹrin dipò agutan kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí.