Exodus 22:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
aládùúgbò náà yóo lọ sí ilé Ọlọrun, yóo sì fi OLUWA ṣẹ̀rí pé òun kọ́ ni òun jí ẹran tí wọn fún òun sìn. Ẹni tí ó fún un ní ẹran sìn yóo faramọ́ ìbúra yìí, kò sì ní gbẹ̀san mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrin ara wọn ni iwájú OLÚWA láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un.