Exodus 22:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí pé ẹ̀wù yìí ni àwọ̀lékè kan ṣoṣo tí ó ní, òun kan náà sì ni aṣọ ìbora rẹ̀. Àbí aṣọ wo ni ó tún ní tí yóo fi bora sùn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ké pè mí, n óo dá a lóhùn, nítorí pé aláàánú ni mí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kìki eyi ni ibora rẹ̀, aṣọ rẹ̀ ti yio fi bora ni: kini on o fi bora sùn? yio si ṣe bi o ba kigbe pè mi, emi o gbọ́; nitori alãnu li emi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara. Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn? Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sími, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi.