Exodus 22:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bákan náà ni àkọ́bí mààlúù rẹ ati ti aguntan rẹ, tí wọ́n bá jẹ́ akọ. Fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ìyá wọn fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ o níláti fi wọ́n rúbọ sí mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ gẹgẹ ni ki iwọ ki o fi akọmalu ati agutan rẹ ṣe: ijọ́ meje ni ki o ba iya rẹ̀ gbọ́; ni ijọ́ kẹjọ ni ki iwọ ki o fi i fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ. Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ kẹjọ.