Exodus 22:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ẹnìkan bá dáná, tí iná náà bá ràn mọ́ koríko, tí ó bá jó oko olóko, tí ó sì jó ọkà tí wọ́n ti kórè jọ tabi tí ó wà lóòró, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ san òmíràn pada fún olóko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iná ba ṣẹ̀, ti o si mu ẹwọn, ti abà ọkà, tabi ọkà aiṣá, tabi oko li o joná; ẹniti o ràn iná na yio san ẹsan nitõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí iná bá ṣẹ́ tí ó kán lu igbó tí ó sì jó àká ọkà tàbí gbogbo oko náà, ẹni tí iná ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò san ohun tí ìná ti ó ṣẹ́ jó padà.