Exodus 23:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
IWỌ kò gbọdọ gbà ìhin eke: máṣe li ọwọ́ si i pẹlu enia buburu lati ṣe ẹlẹri aiṣododo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀: Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburu lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.