Exodus 23:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn li ọdún keje iwọ o jẹ ki o simi, ki o si gbé jẹ; ki awọn talaka enia rẹ ki o ma jẹ ninu rẹ̀: eyiti nwọn si fisilẹ ni ki ẹran igbẹ ki o ma jẹ. Irú bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe si agbalá-àjara, ati agbalá-olifi rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni talákà láàrin yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà-àjàrà rẹ àti ọgbà Olífì rẹ.