Exodus 23:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O níláti máa ṣe àjọ̀dún àìwúkàrà; gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni o gbọdọ̀ fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ ninu oṣù Abibu, nítorí pé ninu oṣù náà ni o jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o kiyesi ajọ aiwukàra: ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, bi mo ti pa a laṣẹ fun ọ, li akokò oṣù Abibu (nitori ninu rẹ̀ ni iwọ jade kuro ni Egipti); a kò gbọdọ ri ẹnikan niwaju mi li ọwọ́ ofo:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣe àjọ̀dún àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Ábíbù, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.