Exodus 23:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Máa fetí sí ohun tí angẹli náà bá sọ fún ọ, kí o sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, má ṣe fi agídí ṣe ìfẹ́ inú rẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé èmi ni mo rán an, kò sì ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi ara lọdọ rẹ̀, ki o si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, máṣe bi i ninu; nitoriti ki yio dari irekọja nyin jì nyin, nitoriti orukọ mi mbẹ lara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fi ara bálẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe sọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìsedédé yín jin yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀.