Exodus 23:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi iwọ o ba gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ nitõtọ, ti iwọ si ṣe gbogbo eyiti mo wi; njẹ emi o jasi ọtá awọn ẹniti nṣe ọtá nyin, emi o si foró awọn ti nforó nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì se ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòrò àwọn tí ń fóòrò yín.