Exodus 23:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
o kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún àwọn oriṣa wọn, o kò sì gbọdọ̀ bọ wọ́n, tabi kí o hu irú ìwà ìbọ̀rìṣà tí àwọn ará ibẹ̀ ń hù. Wíwó ni kí o wó àwọn ilé oriṣa wọn lulẹ̀, kí o sì fọ́ gbogbo àwọn òpó wọn túútúú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò gbọdọ tẹriba fun oriṣa wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn, ki o má si ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: bikoṣepe ki iwọ ki o fọ́ wọn tútu, ki iwọ ki o si wó ere wọn palẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú.