Exodus 23:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o rán ẹ̀ru mi siwaju rẹ, emi o si dà gbogbo awọn enia rú ọdọ ẹniti iwọ o dé, emi o si mu gbogbo awọn ọtá rẹ yi ẹ̀hin wọn dà si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀ta rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ.