Exodus 23:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N kò ní tíì lé wọn jáde fún ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má baà di aṣálẹ̀, kí àwọn ẹranko sì pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo gba gbogbo ilẹ̀ náà mọ́ yín lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju rẹ li ọdún kan; ki ilẹ na ki o má ba di ijù, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba rẹ̀ si ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan soso, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀ jù fún ọ.