Exodus 24:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wí fún Mose pé, “Ẹ gòkè tọ èmi OLUWA wá, ìwọ ati Aaroni, ati Nadabu, ati Abihu, ati aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, kí ẹ sì sin èmi OLUWA ní òkèèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O SI wi fun Mose pe, Goke tọ̀ OLUWA wá, iwọ, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli; ki ẹnyin ki o si ma sìn li òkere rére.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Gòkè tọ OLÚWA wá, ìwọ àti Árónì, Nádábú àti Ábíhù àti àádọ́rin (70) àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.