Exodus 24:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA wí fún Mose pé, “Gun orí òkè tọ̀ mí wá, kí o dúró sibẹ, n óo sì kó wàláà tí wọ́n fi òkúta ṣe fún ọ, tí mo kọ àwọn òfin ati ìlànà sí, fún ìtọ́ni àwọn eniyan yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì sọ fún Mósè pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhín-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní òkúta ìkọ̀wé pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.”