Exodus 24:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ẹ dúró níhìn-ín dè wá títí a óo fi pada wá bá yín. Aaroni ati Huri wà pẹlu yín, bí ẹnikẹ́ni bá ní àríyànjiyàn kan, kí ó kó o tọ̀ wọ́n lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsìí, Árónì àti Húrì ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnikan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.