Exodus 24:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mose bá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, ó dìde, ó tẹ́ pẹpẹ kan sí ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ri ọ̀wọ̀n mejila mọ́lẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si kọwe gbogbo ọ̀rọ OLUWA, o si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si tẹ́ pẹpẹ kan nisalẹ òke na, o mọ ọwọ̀n mejila, gẹgẹ bi ẹ̀ya Israeli mejila.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè kọ gbogbo ohun tí OLÚWA sọ sílẹ̀. Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó se ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.