Exodus 24:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ni Mose bá gba ẹ̀jẹ̀ ẹran yòókù tí ó wà ninu àwo, ó wọ́n ọn sí àwọn eniyan náà lára, ó ní, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí OLUWA bá yín dá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí mo sọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”